18 Jòhánù lo oríìṣíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.
19 Ṣùgbọ́n nígbà ti Jòhánù bú Hẹ́rọ́dù tetírakì, tí ó bá wí nítorí Hérọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Hẹ́ródù tí ṣe,
20 Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ ní tí ó fi Jòhánù sínú túbú.
21 Nígbà tí a sì ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamtíìsì Jésù pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,
22 Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
23 Jésù tìkara rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Jósẹ́fù,tí í ṣe ọmọ Élì,
24 Tí í ṣe ọmọ Mátatì,tí í ṣe ọmọ Léfì, tí í ṣe ọmọ Melíkì,tí í ṣe ọmọ Janà, tí í ṣe ọmọ Jóṣẹ́fù,