9 Àti nísinsìnyí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a ké e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ jù sínú iná.”
10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ha ṣe?”
11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14 Àwọn ọmọ-ogun sì bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kíni àwa ó ṣe?”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùneké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
15 Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Jòhánù, bí òun ni Kírísítì bí òun kọ́;