1 Ní ọjọ́ ìsinmi kan, Jésù ń kọjá láàrin oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.
2 Àwọn kan nínú àwọn Farisí sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”
3 Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkárarẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀;
4 ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà níkan ṣoṣo?”