28 Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín.
29 Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, pa èkejì dà sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù rẹ pẹ̀lú.
30 Sì fifún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ lẹ́rù, má sì ṣe padà bèèrè.
31 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.
32 “Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn.
33 Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́sẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
34 Bí ẹ̀yin bá wín fún ẹni tí ẹ̀yin ń reti láti rí gbà padà, ọpẹ́ kínni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́sẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́sẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà.