35 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀ta yín kí ẹ̀yin sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ ọ̀gá ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣeun fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.
36 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.
37 “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dáni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín.
38 Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín; òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín: nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.”
39 Ó sì pa òwe kan fún wọn: “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?
40 Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí ó ba pé, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.
41 “Èéṣe tí ìwọ sì ń wo èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú ara rẹ?