23 Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ Jòhánù padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Jòhánù pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Iféfèé tí afẹ́fẹ́ ń mì?
25 Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!
26 Ṣùgbọ́n kíni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!
27 Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:“ ‘Wò ó, mo rán oníṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ;ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
28 Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọju Jòhánù Onítẹ̀bọmi lọ: ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀ jù ú lọ.”
29 (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Jòhánù tẹ̀ wọn bọ mi.