29 (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Jòhánù tẹ̀ wọn bọ mi.
30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisí àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitísí wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)
31 Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?
32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,ẹ̀yin kò sọkún!’
33 Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’
34 Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, Ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́sẹ̀!” ’
35 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo dá a nipa ọgbọ́n tí ó lò.”