38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.
39 Nígbà tí Farisí tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40 Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
41 “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.
42 Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríji àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, tani yóò fẹ́ ẹ jù?”
43 Símónì dáhùn wí pé, “Mo ṣebí ẹni tí ó dáríjìn jù ni.”Ó wí fún un pé, “O wí i re.”
44 Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Símónì pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹṣẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n òun, omije rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi n nù wọ́n nù.