29 (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì dá gbogbo ìdè náà, ẹmi ẹ̀sù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).
30 Jésù sì bí i pé, “Orúkọ rẹ?” Ó sì dáhùn pé,“Léjíónì,” nítorí ẹ̀mí ẹ̀ṣù púpọ̀ ni ó ti wọ̀ ọ́ lára lọ.
31 Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun.
32 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì yọ̀ǹda fún wọn.
33 Nígbà tí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ: agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.
34 Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó sẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà.
35 Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jésù wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bá ẹsẹ̀ Jésù, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n.