15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
16 Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.
17 Jésù sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
19 Bí Ó sì ti rìn ṣíwájú díẹ̀, ní etí òkun, Ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.
20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀lé e.
21 Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapanámù, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsimi, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó sì ń kọ́ni.