Róòmù 10 BMY

1 Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi ni pé, kí àwọn Júù rí ìgbàlà.

2 Mo mọ irú ìfẹ́ àti ìtara tí wọ́n ní sí ọlá àti ògo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìsìnà ni wọn ń gbà wá Ọlọ́run;

3 Ìdí ni pé, wọ́n ń gbìyànjú láti hu ìwà rere nípa pípa òfin àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn Júù mọ́, kí wọn báà lè rí ojú rere Ọlọ́run. Kò yé wọn pé, Kírísítì ti kú láti mú wọn dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run. Òfin àwọn Júù àti àṣà ìbílẹ̀ wọn kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run lè fi gba ènìyàn là.

4 Títí ìsinsin yìí, wọn kò ì tíì mọ̀ pé, Kírísítì kú láti pèsè ohun gbogbo tí wọ́n ń fi àníyàn wá kiri nípa òfin fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ó ti fi òpin sí gbogbo rẹ̀.

5 Nítorí pé Mósè kọ ọ́ pé, “Kí ènìyàn tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà (nípa òfin) gbà, ó ní láti ja àjàṣẹ́gun nínú gbogbo ìdánwò, kí ó sì wà láì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan soso nínú gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.”

6 Ṣùgbọ́n ìgbàlà tí ó wà nípa ìgbàgbọ́ wí pé, “A kò níláti lọ wá inú ọ̀run láti mú Kírísítì wá sí ayé kí ó bá à lè ràn wá lọ́wọ́.”

7 Bẹ́ẹ̀ ni, a kò níláti wọ ìsà òkú lọ láti jí Kírísítì dìde.

8 Nítorí pé, ìgbàlà tí ènìyàn ń ní nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Kírísítì, ìgbàlà tí àwa ń wàásù rẹ̀, wà ní àrọ́wọ́tó ẹnikọ̀ọ̀kan wa. Kódà, ó kínlẹ̀ sí wa tó bí ọkàn àti ẹnu wa ti kínlẹ̀ sí wa.

9 Nítorí pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Olúwa ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jésù Kírísítì ní Olúwa rẹ, a ó gbà ọ́ là.

10 Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú.

11 Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀; ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé.”

12 Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà; Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀.

13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

14 Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù?

15 Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere!”

16 Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìn rere. Nítorí Ìsáià wí pé, “Olúwa, tali ó gba ìyìn wa gbọ́?”

17 Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18 Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ayé.”

19 Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ísírẹ́lì kò ha mọ̀ bí? Mósè ni ó kọ́ wí pé,“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”

20 Ṣùgbọ́n Ìsáià tilẹ̀ láyà, ó wí pé,“Àwọn tí kò wá mi rí mi;Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”

21 Ṣùgbọ́n nípa ti Ísírẹ́lì ni ó wí pé,“Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọnaláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16