Róòmù 9 BMY

1 Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ìbátan mi nípa ti ara, ó wù mí púpọ̀ láti rí i pé ẹ gba Kírísítì gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Lórí Ìpinnu Àti Ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run

2 Ọkàn mi gbọgbẹ́, mo sì ń joró lọ́sán àti lóru nítorí yín.

3 Mo fẹ́ lọ sọ pé ó sàn fún mi kí a yọ orúkọ mi kúrò nínú ìwé Ìyè, kí ẹ̀yin lè rí ìgbàlà. Kírísítì pàápàá àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú mọ̀ pé òtítọ́ ọkàn mi ni èmi ń sọ yìí.

4 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti fi fún yín: Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ẹ kì yóò tẹ́tí sí i. Ó yàn yín bí ẹni ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀. Ó sìn yín (la ihà já) pẹ̀lú ìtànsán ògo rẹ̀, ó mú kí ó dá a yín lójú pé òun yóò bù kún yín, ó fi òfin fún yín kí ẹ le mọ ìfẹ́ rẹ̀ lójojúmọ́, ó yọ̀ǹda fún yín láti sin òun pẹ̀lú ìpinnu ńlá.

5 Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́. Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́. Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo. Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé.

6 Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá íṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Ísírẹ́lì wá, àwọn ni Ísírẹ́lì:

7 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ: “Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀.”

8 Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ.

9 Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

10 Kì sì íṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa;

11 Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, (kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kòse ti ẹni tí ńpeni;)

12 A ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

13 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jákọ́bù ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kóríra.”

14 Njẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìsòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri!

15 Nítorí ó wí fún Mósè pé,“Èmi ó sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún,èmi yóò sì se ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò se ìyọ́nú fún.”

16 Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í se ti ẹni tí ń sáré, bí kò se ti Ọlọ́run tí ń sàánú.

17 Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Fáráò pé, Nítorí èyí ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, kí a sì le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.

18 Nítorí náà ni ó ṣe sàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú lí ọkàn le.

19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, kínni ó ha tún bá ni wí fún? Nítorí tani ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?

20 Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? Ohun tí a mọ, a máa wí fún ẹni tí ó mọ ọn pé, Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyì?

21 Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá?

22 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun;

23 Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo,

24 Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú?

25 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé,“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

26 Yóò sì ṣe,“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’níbẹ̀ ni a ó gbé ti sọ fún wọn pé,ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

27 Ìsáíà sì kí gbe nnítorí Ísírẹ́lì pé:“Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí bí iyanrìn etí òkun,apákan ni ó gbàlà.

28 Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

29 Àti bí Ìsáià ti wí tẹ́lẹ̀:“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọnỌmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,àwa ìbá ti dàbí Sódómù,a bá sì ti sọ wá dàbí Gòmórà.”

30 Ǹjẹ́ kílí àwa ó ha wí? Pé àwọn aláìkọlà, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá ni.

31 Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo,

32 Nítorí kíni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ni;

33 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn subú kalẹ̀ ní Síónì,ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16