Róòmù 3 BMY

Ìsòtítọ́ Ọlọ́run

1 Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ?

2 Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.

3 Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí?

4 Kí a má rí i: kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”

5 Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìsòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn).

6 Kí a má rí i: bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé?

7 Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́sẹ̀?

8 Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bí wọn tọ́.

Kò Sí olóòótọ́ Kan.

9 Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn wọn bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fi hàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

10 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan

11 Kò sí ẹni tí òye yé,kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

12 Gbogbo wọn ni ó ti yapa,wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;kò sí ẹni tí ń ṣe rere,kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

13 “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní Ọ̀fun wọn:ahọ́n wọn di aláìlérè; kò sí ẹni ìtànjẹ.”“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

14 “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

15 “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:

16 Ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

17 Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”

18 “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

19 Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

20 Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

Ìsòdodo Nípa Ìgbàgbọ́.

21 Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì;

22 Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀:

23 Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run:

24 Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù:

25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:

26 Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́.

27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.

28 Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.

29 Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:

30 Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

31 Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16