Róòmù 13 BMY

Síṣe Ìgbọ́ran Sí Àwọn Aláṣẹ

1 Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá.

2 Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn.

3 Nítorí pé adájọ́ kò wá láti dẹ́rù ba àwọn ẹni tí ń se rere. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe búburú yóò máa bẹ̀rù rẹ̀ nígbà gbogbo. Nítorí ìdí èyí, pa òfin mọ́ ìwọ kò sì ní gbé nínú ìbẹ̀rù.

4 Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti ṣe ọ́ ní rere. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣé nǹkan búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò ru idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nííse, ìránṣẹ́ ìbínú sí ara àwọn ẹni tí ń ṣe búburú.

5 Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tẹríba fún àwọn alásẹ, kì í ṣe nítorí ìjìyà tó lé wáyé nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí-ọkàn pẹ̀lú.

6 San owó orí rẹ pẹ̀lú nítorí ìdí méjì pàtàkì tí a ti sọ wọ̀nyí. Nítorí pé ó se dandan kí a san owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Èyí yóò mú kí wọn tẹ̀ṣíwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run náà. Wọn yóò sì máa tọ́jú yín.

7 Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí: owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀

Ẹ Jẹ Gbésè Ìfẹ́

8 Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ní nígbésè, yàtọ̀ fún gbésè ìfẹ́ láti fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já.

9 Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”

10 Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.

11 Àti èyí, bí ẹ ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsìnyí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsìn yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ.

12 Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀.

13 Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmọ̀tipara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì íṣe ní ìjà àti ìlara.

14 Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jésù Kírísítì Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti ma mú ìfẹ́kúfẹ rẹ̀ ṣẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16