1 Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà.
2 Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.
3 Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù.
4 Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.
5 Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn.Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà.
6 Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin.
7 Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.
8 Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.
9 Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì.
10 Ẹ kí Ápẹ́lẹ́sì, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kírísítì.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Árísítóbúlúsì.
11 Ẹ kí Héródíónì, ìbátan mi.Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Nákísísù tí wọ́n wá nínú Olúwa.
12 Ẹ kí Tírífẹ́nà àti Tírífósà, àwọn obìrin tí wọ́n se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.Ẹ kí Pásísì ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
13 Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀pú.
14 Ẹ kí Ásínkírítúsì, Fílégónì, Hérímésì, Pátíróbà, Hérímásì àti àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.
15 Ẹ kí Fílólóhù, àti Júlíà, Néréù, àti arábìnrin rẹ̀, àti Ólíḿpà, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.
16 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.Gbogbo ìjọ kírísitì kí yín.
17 Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn.
18 Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kírísítì Olúwa wa, bí kò se ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ geere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.
19 Nítorí ìgbọ́ràn yín tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo., nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.
20 Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.
21 Tìmótíù alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lúkíúsì, àti Jásónì, àti Sósípátérù, àwọn ìbátan mi, kí yín.
22 Èmi Térítíù tí ń kọ Èpísítélì yí, kí yín nínú Olúwa.
23 Gáíúsì, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó se náà fi ìkíni ránsẹ́.Érásítù, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó isẹ́ ìlú, àti arákùnrin wa Kúárítù fi ìkíni wọn ránsẹ́.
24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
25 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìn rere mi àti ìpolongo Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,
26 ṣùgbọ́n, nísinsinyí, a ti fihàn, a sì ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbàgbọ́, kí wọn sì le se ìgbọ́ràn sí i pẹ̀lú;
27 kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnì kan ṣoṣo tí ọgbọ́n í se tirẹ̀ nípa Jésù Kírísítì! Àmín.