Róòmù 1 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìkíni Pọ́ọ̀lù Sí Àwọn Àyànfẹ́

1 Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì ẹni tí a ti pè láti jẹ́ Àpósítélì, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run.

2 Ìyìnrere tí a ti pinnu láti ẹnu àwọn wòlíì nínú ìwé Mímọ́ láti ìgbà pípẹ́ ṣáájú ìsinsin yìí.

3 Nípa ìfiyèsí ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ìran Dáfídì nípa ìbí ti ènìyàn.

4 Ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹmi ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jésù Kírísítì Olúwa wa.

5 Láti ọdọ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ Àpósítélì gbà, láti wàásù fún gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè kí wọn kí ó lè wá sínú ìgbàgbọ́ èyíni ní orúkọ rẹ̀.

6 Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jésù Kírísítì.

7 Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Róòmù tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

Ìfojúsọ́nà Pọ́ọ̀lù Láti Bẹ Róòmù Wò

8 Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Jésù kírísítì fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

9 Ọlọ́run, ẹni tí èmí ń sìn tí mo sì fi gbogbo ọkàn mi jìn fún un láti máa wàásù ìyìnrere ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsinmi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi

10 nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó sí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

11 Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa,

12 èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

13 Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù.

14 Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Gíríkì àti sí àwọn ẹlòmíràn tí kì í se Gíríkì, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aláìgbọ́n.

15 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Róòmù àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìn rere Ọlọ́run sí i yín.

16 Èmi kò tijú ìyìn rere Jésù, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún aláìkọlà pẹ̀lú.

17 Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́rùn ti farahàn, òdodo Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

Ìbínú Ọlọ́run Sí Orílẹ̀ Ayé.

18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.

19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn.

20 Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

21 Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáadáa, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń rò èrò aṣiwèrè, ọkàn òmùgọ̀ wọn sì ṣókùnkùn.

22 Wọ́n Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá.

23 wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kìí díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́.

25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń forí balẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

26 Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́ ìwàkíwà: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò àdánidá padà sí èyí tí ó lòdì sí ti àdánidá:

27 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

28 Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe:

29 Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àránkan; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà-búburú; wọ́n jẹ́ afi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́.

30 Asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, akóríra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí,

31 Aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú:

32 Bí ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16