Róòmù 6 BMY

Ikú Sí Ẹ̀sẹ̀, Ìyè Nínú Kírísítì

1 Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jòkòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i?

2 Kò lè rí bẹ́ẹ̀. Ṣé a tún le máa dẹ́sẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀?

3 Nítorí a ti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a di Kírísítẹ́nì tí a sì ṣe ìrìbọmi fún wa láti di apá kan Jésù Kírísítì nípasẹ̀ ikú rẹ̀, a borí agbára ìwà ẹ̀ṣẹ̀.

4 Ẹ ti gbé ògbólógbòó ara yín tí ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ sin pẹ̀lú Kírísítì nígbà tí òun kú, àti nígbà tí Ọlọ́run Baba pẹ̀lú agbára ògo mú un padà sí ìyè, a sì fún yín ní ìyè tun tun rẹ̀ láti gbádùn rẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ nípa ìrìbọmi yín.

5 Nítorí pé ẹ̀yin ti di apá kan ara rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde.

6 Gbogbo èrò burúkú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́sẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

7 Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́

8 Níwọ̀n ìgbà tí ògbólógbòó ara yín tó ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ ti kú pẹ̀lú Kírísítì, àwa mọ̀ pé, ẹ̀yin yóò pín nínú ìyè titun rẹ̀.

9 Kírísítì ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́.

10 Kírísítì kú lẹ́ẹ̀kan soso, láti sẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láàyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11 Nítorí náà, ẹ máa wo ògbólógbòó ara ẹ̀ṣẹ̀ yín gẹ́gẹ́ bí òkú tí kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Dípò èyí, máa gbé ìgbé ayé yín fún Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in fún un, nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa.

12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀sẹ̀ jọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ̀ rẹ̀.

13 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ìkà, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ǹda wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára.

14 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

Erú Sí Ìsòdodo.

15 Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsinyìí, a lè tẹ̀ṣíwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láì bìkítà? (Nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run)

16 Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ (pẹ̀lú ikú) tàbí ìgbọ́ràn (pẹ̀lú ìdáláre). Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá yọ̀ǹda ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀.

17 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti se ìgbọ́ràn, pẹ̀lú ọkàn yín, sí ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́.

18 Nísinsìnyìí, ẹ ti dòminira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

19 Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́.

20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin kò ṣe wàhálà púpọ̀ pẹ̀lú òdodo.

21 Àti pé, kí ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ̀n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsìnyìí láti ronu nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń sọ nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé.

22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.

23 Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16