Róòmù 8 BMY

Ìyè Nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí

1 Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsinyìí fún àwọn tí ó wà nínú Kírísitì.

2 Nítorí nípaṣẹ̀òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kírísítì Jésù ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

3 Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkara rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara,.

4 Kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa ve gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.

5 Àwọn tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń e gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí.

6 Ṣíṣe ìgbọ́ran sí ẹ̀mí Mímọ́ ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà. Ṣùgbọ́n títẹ̀lé ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ náà ń yọrí sí ikú.

7 Nítorí pé ara ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú wa ń tako Ọlọ́run.

8 Ìdí nì yìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìfẹ́ ibi wọn, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.

9 Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ara titun yín ni yóò máa se àkóso yín bí ẹ bá ń rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń gbé inú yín (Ẹ rántí pé, bí ẹnìkan kò bá ní ẹ̀mí Kírísítì tí ń gbé inú rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í se ọmọ-ẹ̀yìn Kirísítì rárá.)

10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kírísítì ń gbé inú yín ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹran ara yín yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo.

11 Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín.

12 Nítorí náà ará, kò jẹ́ ọ̀rọ̀ iyàn fún un yín láti se nǹkan tí ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ń rọ̀ yín láti se.

13 Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì sègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípaṣẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yin sẹ́gun ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀ nínú yín, ẹ̀yin yóò yè.

14 Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run.

15 Àti pé, àwa kò ní láti dàbí ẹrú tó ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ̀gá rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ní láti hùwà bí ọmọ Ọlọ́run. Ẹni tí a sọdọmọ sí ìdílé, Ọlọ́run tó sì ń pe Ọlọ́run ní “Baba, Baba.”

16 Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, ní tòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.

17 Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀. Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀.

Ìgbádùn tí ń bọ̀ fún Kírísítẹ́nì

18 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn.

19 Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.

20 Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.

21 Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkáararẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdibàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

22 Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí.

23 Kì í se àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkara wa pẹ̀lú, tí ó nbí àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkara wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìṣọdọmọ àní ìdáńdè ara wa.

24 Nítorí ìrètí tí a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í se ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí?

25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Dájú

26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa.

27 Ẹni tí ó sì ń wá ọkàn wò, ó mọ ohun ti inú ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń siṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

29 Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, u kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀

30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kírísítì kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

31 Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

32 Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le sòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?

33 Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dárí jì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

34 Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run. Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀.

35 Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì? Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá. Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa? Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí?

36 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé:“Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà.Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa.”

37 Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa.

38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kò sí ohunkóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ rẹ̀. Kì í se ikú tàbí ìyè. Àwọn ańgẹ́lì àti gbogbo agbára ọ̀run àpáàdì fún raarẹ̀ kò le ya ìfẹ́ Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ wa. Ìbẹ̀rù fún wa lónìí, wàhálà nípa ti ọjọ́ ọ̀la.

39 Tí ìsòro bá tilẹ̀ ga ju àwọ̀ sánmọ̀ lọ tàbí ní ìsàlẹ̀ omi, ohunkóhun kì yóò lágbára láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Jésù Kírísítì Olúwa fi hàn nígbà tí ó kú fún wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16