1 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má se tọpinpin ìṣiyèméjì rẹ̀.
2 Ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ààyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo: sùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan.
3 Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á.
4 Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ tí kì í se tìrẹ lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun ni dúró, tàbí subú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.
5 Àwọn kan bu ọlá fún ju ọ̀kan lọ, ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú nípa èyí tí ó tọ́ lọ́kàn ara rẹ̀.
6 Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.
7 Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀.
8 Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, yálà ní kíkú tàbí ní yíyè, ti Olúwa ni àwá jẹ́.
9 Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye.
10 Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́? tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ? Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
11 A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:“ ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,’ ni Olúwa wí‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
12 Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
13 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín.
14 Bí ẹni tí ó wà nínú Jésù Olúwa, mo mọ̀ dájú gbangba pé kò sí oùnjẹ tó jẹ́ àìmọ́ nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkẹ́ni ba kà á sí àìmọ́, òun ni ó se àìmọ́ fún.
15 Bí inú arakùnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí ohun tí ìwọ́ jẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má se fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kírísítì kú fún di ẹni ègbé.
16 Má se gba kí a sọ̀rọ̀ ohun tí ó gbà sí rere ní buburu.
17 Nítorí ìjọba ọ̀run kì í se jíjẹ àti mímu, bí kò se nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Èmí Mímọ́,
18 nítorí ẹni tí ó bá sin Kírísítì nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó se ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.
20 Má se dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, sùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.
21 Ó sàn kí a má jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí se ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ subú.
22 Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nípa ohun tí ohun gbà.
23 Ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó se iyèméjì ni a ti dá lẹ́bi tí ó ba jẹ ẹ́, nítorí kò wá nípa ìgbàgbọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti ipa ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀sẹ̀ ni.