Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28 BMY

Ere-Kúsù Ni Mẹ́lítà

1 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mélítà ni a ń pè eré-kùṣù náà.

2 Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn alàìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.

3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sa ìdí ìwọ̀nwọ̀n-igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.

4 Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú àpànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láàyè.”

5 Òun sì gbọn ẹranko náà sínu iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.

6 Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣúbu lulẹ̀ kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

7 Ní agbégbé ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọ́bílíù; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.

8 Ó sì ṣe, baba Pọ́bílíù dubulẹ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Pọ́ọ̀lù wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.

9 Nígbà tí èyí sì ṣe tán, àwọn ìyókù tí ó ni àrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.

10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ́ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.

Ìpadàdé Sí Róòmù

11 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú-omi kan èyí tí ó lo àkókò otútù ní erékùsù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi ti Alekisáńdírà, èyí tí ó àmì èyí tí se òrìsà ìbejì ti Kásítórù òun Pólúkísù.

12 Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sírákúsì, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.

13 Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Régíónì: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Pútéólì.

14 A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ́ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Róòmù.

15 Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúró pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjọ títí wọ́n fi dé Api-fórù àti sí ilé-èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Pọ́ọ̀lù sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.

16 Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ.

Pọ́ọ̀lù Wàásù Ní Róòmù Ní Abẹ́ Ẹ̀sọ́

17 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ: nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá.

18 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi.

19 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Késárì, kì í ṣe pé mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi.

20 Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”

21 Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Jùdíà nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ.

22 Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”

23 Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.

24 Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.

25 Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrin ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Àìṣáyà wí pé:

26 “ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;à ti ni rírí ẹ̀yin yóò rí, ẹ kì yóò sí òye lati mọ̀.”

27 Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,ojú wọn ni wọn sì ti di.Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,kí wọn má ba à fi etí wọn gbọ́,àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,kí wọn má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

28 “Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn Kèfèrì wọ́n ó sì gbọ́.

29 Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jíyàn púpọ̀.”

30 Pọ́ọ̀lù sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.

31 Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jésù Kírísítì Olúwa, ẹnìkan kò dá a lẹ́kun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28