Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20 BMY

Kọjá Ní Makedóníà Àti Gíríkì

1 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà.

2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Gíríkì.

3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní osù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àtibá ọkọ̀-ojú-omi lọ sí Síríà, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedóníà padà lọ.

4 Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà; àti Sékúńdù; àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù; ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù.

A Jí Éútíkù Dìde Nínú Òkú

5 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Tíróáṣì.

6 Àwa sì síkọ̀ láti Fílípì lọ lẹ́yìn ọjọ àkàrà àìwú, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróáṣì ni ijọ́ méje.

7 Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́.

8 Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí a gbé péjọ sí.

9 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Éútíkù sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Pọ́ọ̀lù sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n lójú oorun, ó súbù láti òkè kẹ́ta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.

10 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbà á mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láàyè.”

11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ́ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ.

12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà bọ̀ láàyè, inú gbogbo wọn sì dún lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ìdágbere Pọ́ọ̀lù Sí Àwọn Alàgbà Efésù

13 Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Ásósì, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹṣẹ̀ lọ.

14 Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Ásósì, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Mítílénì.

15 Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ijọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kíósì; ní ijọ́ kejì rẹ̀ a dé Sámósì, a sì dúró ní Tírógílíónì: ni ijọ́ kéjì rẹ̀ a sì dé Mílétù.

16 Pọ́ọ̀lù ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀-ojú omi kọjá ṣí Éféṣù, nítorí ki ó má baà lo àkókò kankan ni Éṣíà: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣééṣe fún un láti wà ní Jerúsálémù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì.

17 Ní àti Mílétù ni Pọ́ọ̀lù ti ránṣẹ́ sí Éféṣù, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá ṣọ́dọ̀ rẹ̀.

18 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkarayín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Éṣíà, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

19 Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù:

20 Bí èmí kò ti fà ṣẹ́yìn láti sọ ohunkohun tí ó ṣàǹfàànì fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

21 Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Gíríkì pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.

22 “Ǹjẹ́ nsṣinsìn yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerúsálémù, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀:

23 Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi.

24 Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run.

25 “Ǹjẹ́ nísìnsìn yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrin ẹni tí èmi tí ń kiri wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́.

26 Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúró nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.

27 Nítorí tí èmi kò fà ṣẹ́yìn láti ṣọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin.

28 Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábòójútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ (ọmọ) rẹ̀ rà.

29 Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ̀ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárin yín, yóò sì tú agbo ká.

30 Láàrin ẹ̀yin tìkárayín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn.

31 Nítorí náà ẹ máa sọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.

32 “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọfẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrin gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.

33 Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni.

34 Ẹ̀yin tìkárayín ṣáà mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi.

35 Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, bí òun tìkararẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”

36 Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.

37 Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

38 Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28