1 Ọkùnrin kan sì wà ni Kesaríà ti a ń pè ní Kọ̀nélíù, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Ítálì.
2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilé tilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.
3 Níwọ̀n wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere ańgẹ́lì Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Kọ̀nélíù!”
4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kí ni, Olúwa?”Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run fún ìrántí.
5 Sì rán ènìyàn nísinsìnyìí lọ sí Jópà, kí wọn sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù.
6 Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7 Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.
8 Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà. A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú.
9 Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:
10 Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran.
11 Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀:
12 Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
13 Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Pétérù; máa pa kí o sì má a jẹ.”
14 Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, “Àgbẹdọ̀, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí.”
15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ́méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀ nù, ìwọ má ṣe pè é léèwọ̀ mọ́.”
16 Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
17 Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé. Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà.
18 Wọn nahùn ń bèèrè bí Símónì tí a ń pè ní Pétérù, wọ̀ níbẹ̀.
19 Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.
20 Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21 Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22 Wọ́n sì wí pé, “Kọ̀nẹ́líù balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ́ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ ańgẹ́lì mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”
23 Nígbà náà ni ó pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Níjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, nínú àwọn arákùnrin ní Jopa sì bá a lọ pẹ̀lú.
24 Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesaríà, Kọ̀nélíù sì ti ń rétí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.
25 Ó sì ṣe bí Pétérù ti ń wọlé, Kọ̀nélíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.
26 Ṣùgbọ́n Pétérù gbé e dìde, ó ni, “Dìde; ènìyàn ni èmi tìkárami pẹ̀lú.”
27 Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ.
28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilé mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́.
29 Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo bèèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
30 Kọ̀nẹ́líù sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.
31 Ó sì wí pé, ‘Kọ̀nélíù, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.
32 Ǹjẹ́ ránsẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù; ó wọ̀ ní ilé Símónì aláwọ léti òkun: nígbà ti ó bá dé, ẹni yóò sọ̀rọ̀ fún ọ.’
33 Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsìnyìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”
34 Pétérù sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojusajú ènìyàn.
35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣisẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.
36 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì (Òun ni Olúwa ohun gbogbo)
37 Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀.
38 Àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Ẹ̀mi Mímọ́ àti agbára; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
39 “Àwa sì ni ẹlẹ́rì gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerúsálémù. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.
40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba.
41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti lọ́wọ́ Ọlọ́run yàn tẹ́lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jindé kúrò nínú òkú.
42 Ó sì paṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe Onídàjọ́ ààyè àti òkú.
43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
44 Bí Pétérù sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
45 Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti ìkọlà tí wọ́n bá Pétérù wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú.
46 Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo.Nígbà náà ni Pétérù dáhùn wí pé,
47 “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin omi, kí a má bamítíìsì àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?”
48 Ó sì pàsẹ kí a bamitíìsì wọn ni orúkọ Jésù Kírísitì. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ijọ́ mélòókan.