Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5 BMY

Ananíyà Àti Sàfírà

1 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Ananíyà, pẹ̀lú Sàfírà aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan,

2 Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apákan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apákan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.

3 Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ananíyà, È é ṣe ti sátánì fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí-Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apákan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?

4 Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? È é há ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣékè sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”

5 Nígbà tí Ananíyà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó subú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́.

6 Àwọn ọdọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.

7 Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.

8 Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”

9 Pétérù sí wí fún un pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.

11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

Àwọn Àpósítélì Wo Ọ̀pọ̀ Sàn

12 A sì ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Sólómónì.

13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.

14 Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.

15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti ẹní kí òjìji Pétérù ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ.

16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.

Wọ́n Ṣe Inúnibínu Sí Àwọn Àpósítélì

17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlúfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sádúsì wọ̀.

18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn àpósítélì wọn sì fi wọ́n sínú túbú.

19 Ṣùgbọ́n ní òru, áńgẹ́lì Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.

20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹ́ḿpìlì kí ẹ sì máa sọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́ré fún àwọn ènìyàn.”

21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ḿpílì lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpèjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn àpósítélì wá.

22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùsọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn pàda wá, wọn sí sọ fún wọn pé,

23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùsọ́ dúró lóde níwájú ilẹ́kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa sí ilẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.”

24 Nígbà tí olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.

25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹ́ḿpílì, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.”

26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olúsọ́, ó sì mú àwọn àpósítélì wá. Wọn kò fi ipá múwọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.

27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn àpósítélì dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlúfáà sì bi wọ́n léèrè.

28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni. Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ń pete àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

29 Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpósítélì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!

30 Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jésù dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbé kọ́ sí orí igi.

31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aladé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdàríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Ísírẹ́lì.

32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti se ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fifún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”

33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbérò láti pa wọ́n.

34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gàmálíẹ́lì, Farisí àti àmofìn, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn àpósítélì bì sẹ́yìn díẹ̀.

35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyèsí ara yín lóhun tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí.

36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Téúdà dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pá a; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán.

37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Júdà ti Gálílì dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì fa ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká.

38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, Ẹ gáfárà fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣúbu.

39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣúbu; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà”

40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn àpósítélì wọlé, wọ́n lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jésù mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.

41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.

42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ḿpílì àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kùn kíkọ́ni àti láti wàásù ìyìn rere náà pé Jésù ni Kírísítì

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28