Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15 BMY

Àjọ Ìgbìmọ̀ Ní Jerúsálémù

1 ÀWỌN ọkùnrin kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arakùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mósè, ẹ̀yin kí yóò lè là.”

2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánabà ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú wọn, wọ́n yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn nínú àpósítélì kí wọn gòkè lọ sí Jerúsálémù, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.

3 Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Féníkè àti Samaríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.

4 Nígbà tí wọn sì dé Jerúsálémù, àti àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

5 Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ẹ̀yà àwọn Farisí tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mósè mọ́.”

6 Àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.

7 Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Pétérù dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́.

8 Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olúmọ-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa.

9 Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárin àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.

10 Ǹjẹ́ nítorí náà è é ṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù?

11 Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jésù àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”

12 Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀rí sí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́-àṣẹ àti iṣẹ́-àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn aláìkọlà.

13 Lẹ̀yìn tí wọn sì dákẹ́, Jákọ́bù dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi:

14 Símóòní ti róyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojúwo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.

15 Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe dédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

16 “ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,èmi ó sì tún àgọ́ Dáfídì pa tí ó ti wó lulẹ̀:èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,èmi ó sì gbé e ró:

17 kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,àti gbogbo àwọn aláìkọlà tí a ń fi orúkọ mi pè.’ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí

18 Ní Olúwa wí, ẹni tí ó sọ gbogbonǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá,

19 “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.

20 Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.

21 Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi.”

Ìwé Tí Àwọn Àjọ Ìgbìmọ̀ Kọ Sí Àwọn Kèfèrí Onígbàgbọ́.

22 Nígbà nàá ni ó tọ́ lójú àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Áńtíókù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà: Júdà ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Básábà, àti Sílà, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.

23 Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé:Àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà,Tí ó jẹ̀ ti aláìkọlà tí ó wà ní Áńtíókù, àti ní Síríà: àti ní Kílíkíà.

24 Níwọ̀n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín lọ́kàn po, (wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣaima pa òfin Mósè mọ́:) ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ:

25 Ó yẹ lójú àwa, bí àwa ti fi ìmọ̀ sọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Bánábà àti Pọ́ọ̀lù àwọn olùfẹ́ wa.

26 Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

27 Nítorí náà àwa rán Júdà àti Sílà àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.

28 Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù kà yín, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì;

29 Kí ẹ̀yin fà sẹ̀yìn kúrò nínú ẹran àpabọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùn-pa, àti nínú àgbérè: nínú ohun tí, bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere.Àlàáfíà.

30 Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Áńtíókù: nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ pọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn.

31 Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà.

32 Bí Júdà àti Sílà tìkara wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.

33 Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.

34 (Ṣùgbọ́n o wú Sílà láti gbé ibẹ̀.)

35 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì dúró díẹ̀ ni Ańtíókù, wọ́n ń kọ́ní, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.

Ìjà láàárin Pọ́ọ̀lù àti Bánábà

36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélóòkán. Pọ́ọ̀lù sì sọ fún Bánábà pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”

37 Bánábà sì pinnu rẹ̀ láti mú Jòhánù lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù.

38 Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Páḿfílíà, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.

39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Bánábà sì mu Máàkù ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Sáípúrọ́sì.

40 Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.

41 Ó sì la Síríà àti Kílíkíà lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28