Ìṣe Àwọn Àpósítélì 6 BMY

Yíyan Àwọn Méje

1 Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùn-sínú wà ní àárin àwọn Gíríkì tí se Júù àti àwọn Hébérù tí se Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.

2 Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábílì.

3 Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.

4 Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

5 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti Fílípì, àti Pírókórù, àti Níkánórù, àti Tímónì, àti Páríménà, àti Níkólásì aláwọ̀se Júù ara Ańtíókù.

6 Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Àpósítélì; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerúsálémù, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.

A Mú Sítéfánù

8 Sítéfánù tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrin àwọn ènìyàn.

9 Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń se ara sínágógù, tí a ń pè ní Líbátaínì. Àwọn Júù Kírénè àti ti Alekisáńdíríà àti ti Kílíkíà, àti ti Ásíà wá, wọ́n ń bá Sítéfánù jiyàn,

10 ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11 Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Sítéfánù ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run.”

12 Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀.

13 Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, ti wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin.

14 Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jésù ti Násárẹ́tì yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mósè fifún wa padà.”

15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókò ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Sítéfánù, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú ańgẹ́lì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28