1 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tàrà sí Kúúsì. Ní ijọ́ kéjì a sì lọ sí Ródésì, àti gba ibẹ̀ lọ sí Pátarà:
2 A rí ọkọ̀ ojú-omi kan tí ń rékọ́ja lọ sí Fonísíà, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì síkọ̀.
3 Nígbà tí àwa sì ń wo Sáípúrọ́sì lókèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Síríà, a sì gúnlẹ̀ ni Tírè; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù ṣílẹ̀.
4 Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ijọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Pọ́ọ̀lù pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerúsálémù.
5 Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.
6 Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.
7 Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tírè, àwa dé Pítólémáì; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ijọ́ kan.
8 Ní ijọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesaríà; nígbà tí á sì wọ ilé Fílípì ajíhìnrere tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.
9 Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúndíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.
10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Ágábù.
11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹṣẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerúsálémù yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fí i lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”
12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ ṣí Jerúsálémù.
13 Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dàhun wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í se fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerúsálémù, nítorí orúkọ Jésù Olúwa.”
14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”
15 Lẹ́yìn ijọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerúsálémù.
16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kéṣáríà bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Múnásónì ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Sàìpúrọ́sì, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa óò dé sí.
17 Nígbà tí a sì dé Jerúsálémù, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá,
18 Ní ijọ́ kejì, a bá Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ Jákọ́bù; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀.
19 Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹsẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrin àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀.
20 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin.
21 Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrin àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mósè sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn.
22 Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá pejọ pọ̀: dájúdájú wọn óò gbọ́ pé, ìwọ dé.
23 Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́;
24 Àwọn ni kí ìwọ mú, ki o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkararẹ ń rìn dédé, ìwọ sì ń pa òfin Mósè mọ́.
25 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùn pa, àti àgbérè.”
26 Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà; ní ijọ́ kéjì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹ́ḿpílì lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olukùlùkù wọn.
27 Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Éṣíà wá rí i ni tẹ́ḿpílì, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un.
28 Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn èniyan, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ́lú ó sì mú àwọn ará Gíríkì wá sí tẹ́ḿpílì, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.”
29 Nítorí wọ́n tí rí Tírófímù ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù mú wá sínú tẹ́ḿpílì.
30 Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdo, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.
31 Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerúsálémù dàrú.
32 Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Pọ́ọ̀lù.
33 Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì bèèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.
34 Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun.
35 Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà-ipá àwọn ènìyàn.
36 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”
37 Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Pọ́ọ̀lù wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí-ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Gíríkì bí?
38 Ìwọ ha kọ ní ara Íjíbítì náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ ṣí ijù?”
39 Ṣùgbọ̀n Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tásọ́sì ilú Kílíkíà, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi ṣí bẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”
40 Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wí pé: