Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25 BMY

Ìjẹ́jọ́ Níwájú Fẹ́sítọ̀ọ́sì

1 Lẹ́yìn ọjọ́ méta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Fésítúsì gòkè láti Kesaríà lọ sì Jerúsálémù,

2 ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù wá síwájú rẹ̀.

3 Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Fẹ́sítúsì, kí ó bá le se ojúrere fuń wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálémù, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà.

4 Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì dáhùn pé, “A pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní Kesaríà, àti pé òun tíkara òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

5 Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”

6 Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesaríà, ni ọjọ́ kéjì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú òun.

7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerúsálémù ṣọ̀kalẹ̀ wá dúró yì í ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, tí wọn kò lè làdí rẹ̀.

8 Pọ́ọ̀lù si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹ́ḿpílì, tàbí sí Késárì”

9 Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

10 Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́-ìdájọ́ Késárì níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú.

11 Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí mo sí ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú: ṣùgbọn bí kò bá sí otítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fí ọ̀ràn mi lọ Késárì.”

12 Lẹ́yìn tí Fẹ́sítúsì ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pé, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Késárì. Ní ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ ó lọ!”

Fẹ́sítúsì wádìí ọ̀rọ̀ níwájú Ọba Ágírípà

13 Lẹ́yìn ijọ́ mélòó kan, Àgírípà ọba, àti Béníkè sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesaríà láti kí Fẹ́sítúsì.

14 Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Fẹ́sítúsì mú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, wí pé, “Fẹ́líkísì fi ọkùnrin kan ṣílẹ̀ nínú túbú.

15 Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerúsálémù, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.

16 “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù láti dá ẹnìkẹ́ni lẹ́bí, kí ẹni tí a fiṣùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri àyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn,

17 Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kéjì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá.

18 Nígbà tí àwọn olùfiṣùn náa dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn.

19 Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jésù kan tí o tí kú, tí Pọ́ọ̀lù tẹnumọ́ pé ó wà láàyè.

20 Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń se ìwàdìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lere pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀.

21 Ṣùgbọ̀n nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ọ̀ràn rẹ lọ Ọ̀gọ́sítù, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pé kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì.”

22 Àgírípà sí wí fún Fésítúsì pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkááramì,” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”

Pọ́ọ̀lù Níwájú Ágírípà

23 Ní ọjọ́ kejì, tí Àgírípà àti Báníkè wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀sọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Fẹ́sítúsì pàṣẹ, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù jáde.

24 Fẹ́sítúsì sì wí pé, “Àgírípà Ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ mi ni Jerúsálémù àti Kesaríà níhìn yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láàyè mọ́.

25 Ṣùgbọ́n èmi rí i pé, kò se ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkárarẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Aúgọ́sítù, mo tí pinnu láti rán an lọ.

26 Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá ṣíwájú yín, àní ṣíwájú rẹ ọba Àgírípà, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí se wádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ.

27 Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28