Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18 BMY

Ní Kóríntì

1 Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ni Aténì, lọ sí Kọ́ríńtì;

2 Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Àkúílà, tí a bí ni Pọ́ńtù, tí ó ti Ìtalì dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Pírísíkílà aya rẹ̀; nítorí tí Kíláúdíù pàsẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Róòmù. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.

3 Nítorí tí òun náà jẹ́ onísẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì nṣíṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́-ọwọ́ wọn.

4 Ó sì ń fọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ fún wọn nínú ṣínágógù lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Gíríkì lọ́kàn padà.

5 Nígbà tí Sílà àti Tímótíù sì tí Makedóníà wá, ọ̀rọ̀ náà ká Pọ́ọ̀lù lára, ó ń fi hàn fún àwọn Júù pé, Jésù ni Kírísítì náà.

6 Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn èmi mọ́: láti ìsinsìnyìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

7 Ó sì lọ kúrò níbẹ, ó wọ ile ọkùnrin kan tí a ń pé ní Títù Júsù, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sínágógù tímọ́tímọ́.

8 Kírísípù, olórí ṣínágọ́gù, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọ́ríńtì, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitíìsì wọn.

9 Olúwa sì sọ fún Pọ́ọ̀lù lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, sá máa sọ, má sì se pá ẹnu rẹ̀ mọ́:

10 Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.”

11 Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdun kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrin wọn.

12 Nígbà tí Gálíónì sì jẹ báalẹ̀ Ákáyà, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dide sí Pọ́ọ̀lù wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́.

13 Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”

14 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fẹ́ dáhùn, Gálíónì wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹyin Júù;

15 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nipa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrará yín; nítorí tí èmi kò fẹ ṣe onídàjọ́ nǹkan báwọ̀nyí.”

16 Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.

17 Gbogbo àwọn Gíríkì sì mú Sósìténì, olórí ṣínágógù, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gálíónì kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.

Pìrìsílà, Àkúílà àti Àpólò

18 Pọ́ọ̀lù sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀-ojúomi lọ si Síríà, àti Pìrìsílà àti Àkúílà pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kéníkíríà: nítorí tí o tí jẹ́jẹ̀ẹ́.

19 Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éféṣù, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀: ṣùgbọ́n òun tìkararẹ̀ wọ inú Sínágọ́gù lọ, ó sì bá àwọn Júù fí ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.

20 Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀;

21 Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, (Èmi kò gbọdọ̀ má ṣe àjọ ọdún tí ń bọ̀ yìí ni Jerúsálémù bí ó tí wù kí ó rí: ṣùgbọ́n) “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì ṣíkọ̀ láti Éfésù.

22 Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Keṣaríà; tí ó gòkè, tí ó sì kí ijọ, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Áńtíókù.

23 Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ, ó lọ, ó sì kọjá lọ láti Gálátíà àti Fírígíà, ó mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.

24 Júù kan sì wà tí a ń pè ni Àpólò, tí a bí ni Alekisáńdíríà, ó wá sí Éféṣù. Ó nì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀-sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀;

25 Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Olúwa dáradára; kìkì bamitíìsímù tí Jòhánù ní ó mọ̀.

26 Ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sínágọ́gù: nígbà tí Àkúílà àti Pìrìskílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀ wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.

27 Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Ákáyà, àwọn arakùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọfẹ lọ́wọ́ púpọ̀,

28 Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé-mímọ́ pé, Jésù ni Kíríṣítí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28