Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19 BMY

Pọ́ọ̀lù Ní Éfésù

1 Nígbà ti Àpólò wà ni Kọ́ríńtì, ti Pọ́ọ̀lù kọjá lọ sí apá òkè-ìlú, ó sì wá ṣí Éfésù: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan;

2 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mi Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

3 Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamítíìsímù wo ni a bamitíìsímù yín sí?”Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitíìsímù tí Jòhánù.”

4 Pọ́ọ̀lù sí wí pé, “Nítọ̀ọ́tọ́, ní Jòhánù fi bamitíìsímù tí ìrònúpìwàdà bamitíìsímù, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kírísítì Jésù.”

5 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitíìsímù wọn lórúkọ Jéṣù Olúwa.

6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

7 Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

8 Nígbà tí ó sì wọ inú Sínágọ́gù lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run.

9 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù.

10 Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Éṣíà gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì.

11 Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyànu,

12 Tóbẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti ìbàǹtẹ́ ara rẹ̀ tọ àwọn ọlọ́kùnrùn lọ, àrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

13 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan alárìnkiri, alẹ́mìí-èṣù jáde, bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jésù Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jésù tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù fi yín bú.”

14 Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Síkẹ́fà, Júù, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga.

15 Ẹmí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jéù èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”

16 Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pá kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

17 Ìròyìn yìí sì di mímọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Gíríkì pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Éfésù; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jésù Olúwa ga.

18 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn.

19 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń se alálùpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn: wọ́n sì sirò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ́n ìwọ̀n fàdákà.

20 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbérú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.

21 Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Pọ́ọ̀lù pínnu nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedóníà àti Ákáyà, òun ó lọ sí Jerúsálémù, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàì má dé Róòmù pẹ̀lú.”

22 Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ ṣí Makedóníà, Tímótíù àti Érásítù, òun tìkararẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà.

Ìrúkèrúdò ní Éfésù

23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.

24 Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà;

25 Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.

26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

27 Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”

28 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”

29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.

30 Nígbà ti Pọ́ọ̀lù sì ń fẹ́ wọ àárin àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un.

31 Àwọn olórí kan ara Éṣíà, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ibi-ìṣeré náà.

32 Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíran: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọ pọ̀.

33 Àwọn kan nínú àwujọ ń gún Alekisáńdérù, tí àwọn Júù tì síwájú, ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣọ̀rọ̀ Alekisáńdérù sì juwọ́ sì wọn, òun ìbá sì wí ti ẹnu rẹ̀ fún àwọn ènìyàn.

34 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn, ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ ṣí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà tí ará Éfésù!”

35 Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, ó ní, “Ẹ̀yin ará Éfésù, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú ará Éfésù ní í ṣe olùsìn Dáyánà òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Júpítérì bọ́ sílẹ̀?

36 Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìwara ṣe ohunkohun.

37 Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣọ̀rọ̀-òdì ṣí òrìṣà wa.

38 Ǹjẹ́ nítorí náà tí Démétíríù, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn-asọ̀ kan sí ẹnìkẹ́ni, ilé-ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.

39 Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́.

40 Nítorí àwa ṣa wà nínú èwu, nítórí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lóní yìí; kò sáá ní ìdí kan tí ìwọ́jọ yìí fi bẹ́ sílẹ̀.”

41 Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28