Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13 BMY

A Rán Bánábà Àti Pọ́ọ̀lù Fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

1 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Áńtíókù; Bánábà àti Síméónì tí a ń pè ni Nígérì, àti Lúkíọ́sì ará Kírénè, àti Mánáénì (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Hẹ́ródù Tétírákì) àti Ṣọ́ọ̀lù.

2 Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”

3 Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.

Ní Sáípúrọ́sì

4 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn mẹ́jẹ̀èjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀-ojú omi lọ sí Sáípúrọ́sì.

5 Nígbà ti wọ́n sì wà ni Sálámísì, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.

6 Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Páfọ̀, wọ́n rí ọkùnrin kan, oṣó, wòlíì èké, Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Baa-Jésù.

7 Ó wà lọ́dọ̀ Ségíù Páúlúsì baálẹ̀ ìlú náà, amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

8 Ṣùgbọ́n Élímù oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa báalẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.

9 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé,

10 “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?

11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí òòrùn ní sáà kan!”Lójúkan náà ìkunkùn àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.

12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.

Ní Písídíà Ti Áńtíókù

13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà: Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù.

14 Nígbà ti wọ́n sì là Págà kọjá, wọ́n wá sí Pìsìdíà ní Áńtíókù. Wọ́n sì wọ inú sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.

15 Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”

16 Pọ́ọ̀lù sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!

17 Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, apá gíga ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,

18 ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrú fún ìwà wọn ní ijù,

19 nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.

20 Gbogbo èyí sì sẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún. Lẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídájọ̀ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samueli wòlíì.

21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bèèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan nínú ẹ̀ya Bẹ́ńjámínì, fún ogójì ọdún.

22 Nígbà ti ó sì mú Ṣọ́ọ̀lù kúrò, ó gbé Dáfídì dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dáfídì ọmọ Jésè ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

23 “Láti inú irú ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jésù Olugbàlà dìde fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

24 Ṣáájú wíwa Jésù ni Jòhánù ti wàásù bamítísímù ìrónúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Isírẹ́lì.

25 Bí Jòhánù sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣèbí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’

26 “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Ábúráhámù, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.

27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerúsálémù, àti àwọn olórí wọn, nítorí ti wọn kò mọ̀ Jésù, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.

28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pílátù láti pá a.

29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀we nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.

30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,

31 Ó sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Gálílì wá sí Jerúsálémù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìn yìí fún àwọn ènìyàn.

32 “Àwa sì mú ìyìn rere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,

33 Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde: Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé:“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;lónìí ni mo bí ọ.’

34 Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé:“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú.’

35 Nítorí ó sì wí nínú Sáàmù mìíràn pẹ̀lú pé:“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.

37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́

38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jésù yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.

39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.

40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41 “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín,iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín.’ ”

42 Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.

43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ.

46 Pọ́ọ̀lù àti Básébà sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.

47 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti paṣẹ̀ fún wa pé:“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”

48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.

49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbégbé náà.

50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Básébà, wọ́n sì ṣí wọn kúrò ni agbégbé wọn.

51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikóníónì.

52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28