8 Nítorí pé, ìgbàlà tí ènìyàn ń ní nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Kírísítì, ìgbàlà tí àwa ń wàásù rẹ̀, wà ní àrọ́wọ́tó ẹnikọ̀ọ̀kan wa. Kódà, ó kínlẹ̀ sí wa tó bí ọkàn àti ẹnu wa ti kínlẹ̀ sí wa.
9 Nítorí pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Olúwa ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jésù Kírísítì ní Olúwa rẹ, a ó gbà ọ́ là.
10 Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú.
11 Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀; ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé.”
12 Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà; Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀.
13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
14 Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù?