1 Ǹjẹ́ mo ní: Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Ísírẹ́lì ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Ábúráhámù, ni ẹ̀yà Béńjámínì.
2 Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé-mímọ́ ti wí ní ti Èlíjà? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, wí pé:
3 “Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan soso ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.”
4 Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un? “Mo ti paẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin ènìyàn mọ́ sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Báálì.”
5 ẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni li àkókò ìsinsin yìí pẹ̀lú, apákan wà nípa ìyànfẹ́ ti ore-ọ̀fẹ́.