29 Nítorí àìlábámọ̀ li ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run.
30 Nítorí gẹ̀gẹ̀ bí ẹyin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí ànú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn.
31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fi hàn yín.
32 Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.
33 A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!Àwámáridí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 “Nítorí tali ó mọ inú Olúwa?Tàbí tani íṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 “Tàbí tani ó kọ́ fifún un,tí a kò sì san padà fún u?”