16 láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.
17 Nítorí náà, mo ní ìsògo nínú Kírísítì Jésù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run.
18 Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi:
19 nípa agbára isẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí a se lọ́wọ́ Ẹ̀mi. Mo ti polongo ìyìn rere Kírísítì ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti Jérúsálẹ́mù dé ìlú tí a ń pè ní Ílíríkónì.
20 Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìn rere Kírísítì ní ibi gbogbo tí wọn kò tí i gbọ́ nípa rẹ̀, kí èmi kí ó má se máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn.
21 Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Àwọn tí kò tí ì sọ òrọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,yóò sì yé àwọn tí kò tí ì gbọ́ ọ rí.”
22 Ìdí nì yìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó wa bẹ̀ yín wò.