18 Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi:
19 nípa agbára isẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí a se lọ́wọ́ Ẹ̀mi. Mo ti polongo ìyìn rere Kírísítì ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti Jérúsálẹ́mù dé ìlú tí a ń pè ní Ílíríkónì.
20 Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìn rere Kírísítì ní ibi gbogbo tí wọn kò tí i gbọ́ nípa rẹ̀, kí èmi kí ó má se máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn.
21 Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Àwọn tí kò tí ì sọ òrọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,yóò sì yé àwọn tí kò tí ì gbọ́ ọ rí.”
22 Ìdí nì yìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó wa bẹ̀ yín wò.
23 Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ ní agbègbè yìí, tí èmi sì ti ń pòùngbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti tọ̀ yín wá,
24 mo gbèrò láti se bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà. Èmi yóò bẹ̀ yín wò ní ọ̀nà ìrìnàjò mi, lẹ́yìn tí a bá sì gbádùn ara wa fún ìgbà díẹ̀, ẹ ó kún mi ọ́wọ́ nínú ìrìnàjò mi láti dé ibẹ̀.