4 Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́.
5 Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin ní ẹ̀mí ìrẹ́pọ̀ láàrin ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jésù Kírísítì,
6 kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
7 Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run.
8 Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀,
9 kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà,Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”