18 Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ mi. Èmi fẹ́ se èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe.
19 Níorí ohun tí èmi se kì í se ohun rere tí èmi fẹ́ láti se; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, éyí nì ni èmi ń se.
20 Nísinsin yìí, bí mo bá ń se nǹkan tí n kò fẹ́ láti se, kì í se ẹ̀mi fúnra mi ni ó se é, bí kò se ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó se é.
21 Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ se rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi.
22 Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run;
23 mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi.
24 Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara ikú yìí?