1 Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ìbátan mi nípa ti ara, ó wù mí púpọ̀ láti rí i pé ẹ gba Kírísítì gbọ́.
2 Ọkàn mi gbọgbẹ́, mo sì ń joró lọ́sán àti lóru nítorí yín.
3 Mo fẹ́ lọ sọ pé ó sàn fún mi kí a yọ orúkọ mi kúrò nínú ìwé Ìyè, kí ẹ̀yin lè rí ìgbàlà. Kírísítì pàápàá àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú mọ̀ pé òtítọ́ ọkàn mi ni èmi ń sọ yìí.
4 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti fi fún yín: Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ẹ kì yóò tẹ́tí sí i. Ó yàn yín bí ẹni ọ̀tọ̀ fún ara rẹ̀. Ó sìn yín (la ihà já) pẹ̀lú ìtànsán ògo rẹ̀, ó mú kí ó dá a yín lójú pé òun yóò bù kún yín, ó fi òfin fún yín kí ẹ le mọ ìfẹ́ rẹ̀ lójojúmọ́, ó yọ̀ǹda fún yín láti sin òun pẹ̀lú ìpinnu ńlá.