21 Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá?
22 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun;
23 Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣájú fún ògo,
24 Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn aláìkọlà pẹ̀lú?
25 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé,“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”
26 Yóò sì ṣe,“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’níbẹ̀ ni a ó gbé ti sọ fún wọn pé,ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”
27 Ìsáíà sì kí gbe nnítorí Ísírẹ́lì pé:“Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá rí bí iyanrìn etí òkun,apákan ni ó gbàlà.