3 Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó.
4 Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.”
5 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ ọba fún Aisaya tán,
6 ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á.
7 Ó ní òun óo fi ẹ̀mí kan sinu rẹ̀, tí yóo mú kí ó sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó bá gbọ́ ìròyìn kan, òun óo sì jẹ́ kí wọ́n pa á nígbà tí ó bá dé ilẹ̀ rẹ̀.”
8 Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i.
9 Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé,