15 Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.
16 Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun.
17 Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya.
18 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina.
19 Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀.
20 Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.