26 Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.
27 Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí:Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́,
28 ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.
29 Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.
30 Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila.
31 Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.
32 Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli.