Àwọn Ọba Kinni 13:23-29 BM

23 Nígbà tí wọ́n jẹun tan, wolii àgbàlagbà yìí di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì fún wolii ará Juda.

24 Wolii ará Juda náà bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó ń lọ. Bí ó ti ń lọ lójú ọ̀nà, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Òkú rẹ̀ wà ní ojú ọ̀nà níbẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà sì dúró tì í.

25 Àwọn ọkunrin kan tí wọn ń kọjá lọ rí òkú ọkunrin yìí lójú ọ̀nà, ati kinniun tí ó dúró tì í. Wọ́n lọ sí ìlú Bẹtẹli níbi tí wolii àgbàlagbà náà ń gbé, wọ́n sì ròyìn ohun tí wọ́n rí fún un.

26 Nígbà tí wolii àgbàlagbà náà gbọ́, ó ní, “Wolii tí ó ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ OLUWA ni. Nítorí náà ni OLUWA fi rán kinniun sí i, pé kí ó pa á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti kìlọ̀ fún un tẹ́lẹ̀.”

27 Ó bá pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ bá mi di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì.” Wọ́n sì bá a di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.

28 Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun.

29 Wolii àgbàlagbà yìí gbé òkú ọkunrin náà sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ó sì gbé e pada wá sí ìlú Bẹtẹli láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ati láti sin ín.