20 Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
21 Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri.
22 Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba.
23 Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́.
24 Lẹ́yìn náà, ó ra òkè Samaria ní ìwọ̀n talẹnti fadaka meji, lọ́wọ́ ọkunrin kan tí ń jẹ́ Ṣemeri. Omiri mọ odi yí òkè náà ká, ó sì sọ orúkọ ìlú tí ó kọ́ náà ní Samaria, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Ṣemeri, ẹni tí ó ni òkè náà tẹ́lẹ̀.
25 Nǹkan tí Omiri ṣe burú lójú OLUWA, ibi tí ó ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
26 Gbogbo ọ̀nà burúkú tí Jeroboamu ọmọ Nebati rìn ni òun náà ń tọ̀. Òun náà jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa tí wọn ń bọ.