27 Àwọn nǹkan yòókù tí Omiri ṣe ati iṣẹ́ akikanju tí ó ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
28 Omiri kú, wọ́n sì sin ín sí Samaria; Ahabu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.
29 Ní ọdún kejidinlogoji tí Asa, ọba Juda gorí oyè ni Ahabu, ọmọ Omiri gorí oyè ní Israẹli, Ahabu sì jọba lórí Israẹli ní Samaria fún ọdún mejilelogun.
30 Ahabu ọmọ Omiri ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA ju gbogbo àwọn tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ.
31 Bí ẹni pé, gbogbo àìdára tí Ahabu ọba ṣe bíi ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, kò burú tó, ó tún lọ fẹ́ Jesebẹli ọmọbinrin Etibaali, ọba Sidoni, ó sì ń bọ oriṣa Baali.
32 Ó tẹ́ pẹpẹ kan fún oriṣa Baali ninu ilé tí ó kọ́ fún oriṣa náà, ní Samaria.
33 Bákan náà, ó tún ṣe oriṣa Aṣera kan. Ahabu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu ju gbogbo àwọn ọba Israẹli tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.