3 “Kúrò níhìn-ín, kí o doríkọ apá ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara pamọ́ lẹ́bàá odò Keriti, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.
4 Ninu odò yìí ni o óo ti máa bu omi mu, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò kan pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”
5 Elija bá lọ, ó ṣe bí OLUWA ti wí, ó sì ń gbé ẹ̀bá odò Keriti, ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.
6 Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ ati ẹran wá fún un ní ojoojumọ, ní àràárọ̀ ati ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi odò náà.
7 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà.
8 OLUWA bá tún sọ fún Elija pé,
9 “Dìde nisinsinyii, kí o lọ sí ìlú Sarefati, ní agbègbè Sidoni, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Mo ti pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀ láti máa fún ọ ní oúnjẹ.”