14 O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.”
15 Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.”
16 Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija.
17 Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!”
18 Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali.
19 Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.”
20 Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli.