Àwọn Ọba Kinni 18:17-23 BM

17 Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!”

18 Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali.

19 Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.”

20 Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli.

21 Elija bá súnmọ́ gbogbo àwọn eniyan, ó wí fún wọn pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi máa ṣe iyèméjì? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni Ọlọrun, ẹ máa sìn ín. Bí ó bá sì jẹ́ pé oriṣa Baali ni ẹ máa bọ ọ́.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò sọ ohunkohun.

22 Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450).

23 Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i.