19 Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀.
20 Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.”Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú.
21 Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.”
22 Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.”
23 Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí.
24 Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.”
25 Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á.