Àwọn Ọba Kinni 20:19-25 BM

19 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn.

20 Olukuluku wọn pa ẹni tí ó dojú ìjà kọ. Àwọn ọmọ ogun Siria bá sá. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sì ń lé wọn lọ. Ṣugbọn Benhadadi, ọba Siria, ti gun ẹṣin sá lọ, pẹlu àwọn jagunjagun tí wọ́n gun ẹṣin.

21 Ahabu ọba bá lọ sójú ogun, ó kó ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun; ó ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Siria, ó sì pa ọpọlọpọ ninu wọn.

22 Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.”

23 Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn.

24 Nítorí náà, mú àwọn ọba mejeejilelọgbọn kúrò ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí olórí ogun, kí o sì fi àwọn ọ̀gágun gidi dípò wọn.

25 Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.”Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí.